诗篇 114
以色列出埃及的时候
Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti, ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè 2Juda wà ní ibi mímọ́, Israẹli wà ní ìjọba. 3Òkun sì rí i, ó sì wárìrì: Jordani sì padà sẹ́yìn.
4Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn. 5Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì? Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn? 6Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò, àti ẹ̀yin òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn?
7Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa; ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu 8tí ó sọ àpáta di adágún omi, àti òkúta-ìbọn di orísun omi.
已复制!
Aa